Esekiẹli 30:15
Ezekiel 30:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu ìlú odi Ejibiti èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò.
Ezekiel 30:15 in English
Ezekiel 30:15 · Berean Standard Bible
I will pour out My wrath on Pelusium,* the stronghold of Egypt, and cut off the crowds of Thebes.
Context
13“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run,
Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi.
Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti,
Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà. 14Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro,
èmi yóò fi iná sí Ṣoani,
èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi. 15Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu
ìlú odi Ejibiti
èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò. 16Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti
Pelusiumu yóò japoró ní ìrora.
Ìjì líle yóò jà ní Tebesi
Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo. 17Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti
yóò ti ipa idà ṣubú
wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.