Native Bible

Ezekiel 30:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro, èmi yóò fi iná sí Ṣoani, èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi.

Ezekiel 30:14 in English

Ezekiel 30:14 · Berean Standard Bible

I will lay waste Pathros, set fire to Zoan, and execute judgment on Thebes.*

Context

12Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ, Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú: láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn, Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò. Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́. 13“ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run, Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi. Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti, Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà. 14Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro, èmi yóò fi iná sí Ṣoani, èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi. 15Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu ìlú odi Ejibiti èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò. 16Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti Pelusiumu yóò japoró ní ìrora. Ìjì líle yóò jà ní Tebesi Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.