Native Bible

Ezekiel 30:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti Pelusiumu yóò japoró ní ìrora. Ìjì líle yóò jà ní Tebesi Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo.

Ezekiel 30:16 in English

Ezekiel 30:16 · Berean Standard Bible

I will set fire to Egypt, Pelusium will writhe in anguish, Thebes will be split open, and Memphis will face daily distress.

Context

14Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro, èmi yóò fi iná sí Ṣoani, èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi. 15Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu ìlú odi Ejibiti èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò. 16Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti Pelusiumu yóò japoró ní ìrora. Ìjì líle yóò jà ní Tebesi Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo. 17Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti yóò ti ipa idà ṣubú wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn. 18Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò; níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.