Native Bible

Ezekiel 28:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?

Ezekiel 28:3 in English

Ezekiel 28:3 · Berean Standard Bible

Behold, you are wiser than Daniel; no secret is hidden from you!

Context

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. 3Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí? Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ? 4Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ, ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ, àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà, nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ. 5Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.