Esekiẹli 28:2
Ezekiel 28:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi, ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà, ní àárín gbùngbùn Òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Ezekiel 28:2 in English
Ezekiel 28:2 · Berean Standard Bible
“Son of man, tell the ruler of Tyre that this is what the Lord GOD says: Your heart is proud, and you have said, ‘I am a god; I sit in the seat of gods in the heart of the sea.’ Yet you are a man and not a god, though you have regarded your heart as that of a god.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi,
ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;
Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà,
ní àárín gbùngbùn Òkun.”
Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. 3Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?
Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ? 4Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,
ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,
àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,
nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.