Esekiẹli 28:5
Ezekiel 28:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ, ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè, nítorí ọrọ̀ rẹ.
Ezekiel 28:5 in English
Ezekiel 28:5 · Berean Standard Bible
By your great skill in trading you have increased your wealth, but your heart has grown proud because of it.
Context
3Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?
Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ? 4Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,
ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,
àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,
nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ. 5Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,
ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
ọkàn rẹ gbé sókè,
nítorí ọrọ̀ rẹ. 6“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,
pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. 7Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,
ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;
wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,
ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,
wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.