Esekiẹli 28:7
Ezekiel 28:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè; wọn yóò yọ idà wọn sí ọ, ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ, wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
Ezekiel 28:7 in English
Ezekiel 28:7 · Berean Standard Bible
behold, I will bring foreigners against you, the most ruthless of nations. They will draw their swords against the beauty of your wisdom and will defile your splendor.
Context
5Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,
ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
ọkàn rẹ gbé sókè,
nítorí ọrọ̀ rẹ. 6“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,
pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. 7Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,
ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;
wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,
ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,
wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́. 8Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò,
ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná,
àwọn tí a pa ní àárín Òkun. 9Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”
ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?
Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,
ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.