Native Bible

Ezekiel 28:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò, ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná, àwọn tí a pa ní àárín Òkun.

Ezekiel 28:8 in English

Ezekiel 28:8 · Berean Standard Bible

They will bring you down to the Pit, and you will die a violent death in the heart of the seas.

Context

6“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n, pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run. 7Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè; wọn yóò yọ idà wọn sí ọ, ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ, wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́. 8Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò, ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná, àwọn tí a pa ní àárín Òkun. 9Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́. 10Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà, ní ọwọ́ àwọn àjèjì. Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.