Esekiẹli 21:15
Ezekiel 21:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun. Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun.
Ezekiel 21:15 in English
Ezekiel 21:15 · Berean Standard Bible
So that their hearts may melt and many may stumble, I have appointed at all their gates a sword for slaughter. Yes, it is ready to flash like lightning; it is drawn for slaughter.
Context
13“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’ 14“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn,
sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́.
Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì,
kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta.
Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn
idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀,
tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún. 15Kí ọkàn kí ó lè yọ́
kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀,
mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun.
Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná,
a gbá a mú fún ìparun. 16Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún
kí o sì jà sí òsì
lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ. 17Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́
ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀.
Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.