Esekiẹli 21:13
Ezekiel 21:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’
Ezekiel 21:13 in English
Ezekiel 21:13 · Berean Standard Bible
Surely testing will come! And what if even the scepter, which the sword despises, does not continue?’ declares the Lord GOD.
Context
11“ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,
kí ó lè ṣe é gbámú;
a pọ́n ọn, a sì dán an,
ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani. 12Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn,
nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi;
yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli
ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi
nítorí idà náà;
nítorí náà lu oókan àyà rẹ. 13“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’ 14“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn,
sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́.
Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì,
kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹta.
Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn
idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀,
tí yóò sé wọn mọ́ níhìn-ín àti lọ́hùnnún. 15Kí ọkàn kí ó lè yọ́
kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀,
mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun.
Háà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná,
a gbá a mú fún ìparun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.