Esekiẹli 21:11
Ezekiel 21:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n, kí ó lè ṣe é gbámú; a pọ́n ọn, a sì dán an, ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.
Ezekiel 21:11 in English
Ezekiel 21:11 · Berean Standard Bible
The sword is appointed to be polished, to be grasped in the hand. It is sharpened and polished, to be placed in the hand of the slayer.
Context
9“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, èyí yìí ní Olúwa wí pé,
“ ‘Idà kan, idà kan,
tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú, 10a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀,
a dán an láti máa kọ mọ̀nà!
“ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀. 11“ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n,
kí ó lè ṣe é gbámú;
a pọ́n ọn, a sì dán an,
ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani. 12Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn,
nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi;
yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli
ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi
nítorí idà náà;
nítorí náà lu oókan àyà rẹ. 13“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Juda èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ̀síwájú mọ́ ń kọ́? Ni Olúwa Olódùmarè wí.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.