Native Bible

Ezekiel 21:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀, a dán an láti máa kọ mọ̀nà! “ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀.

Ezekiel 21:10 in English

Ezekiel 21:10 · Berean Standard Bible

it is sharpened for the slaughter, polished to flash like lightning! Should we rejoice in the scepter of My son? The sword despises every such stick.

Context

8Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé: 9“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, èyí yìí ní Olúwa wí pé, “ ‘Idà kan, idà kan, tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú, 10a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀, a dán an láti máa kọ mọ̀nà! “ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀. 11“ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n, kí ó lè ṣe é gbámú; a pọ́n ọn, a sì dán an, ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani. 12Sọkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn, nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi; yóò wá sórí gbogbo ọmọ-aládé Israẹli ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi nítorí idà náà; nítorí náà lu oókan àyà rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.