Native Bible

Ezekiel 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé:

Ezekiel 21:8 in English

Ezekiel 21:8 · Berean Standard Bible

Again the word of the LORD came to me, saying,

Context

6“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn. 7Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa Olódùmarè wí.” 8Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé: 9“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, èyí yìí ní Olúwa wí pé, “ ‘Idà kan, idà kan, tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú, 10a pọ́n láti pa ènìyàn púpọ̀, a dán an láti máa kọ mọ̀nà! “ ‘Àwa o ha máa ṣe àríyá ọ̀gọ ọmọ mi? Idà gán gbogbo irú igi bẹ́ẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.