Native Bible

Ezekiel 21:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.

Ezekiel 21:6 in English

Ezekiel 21:6 · Berean Standard Bible

But you, son of man, groan! Groan before their eyes with a broken heart and bitter grief.

Context

4Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúúsù títí dé àríwá. 5Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’ 6“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn. 7Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa Olódùmarè wí.” 8Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé:

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.