Esekiẹli 21:7
Ezekiel 21:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa Olódùmarè wí.”
Ezekiel 21:7 in English
Ezekiel 21:7 · Berean Standard Bible
And when they ask, ‘Why are you groaning?’ you are to say, ‘Because of the news that is coming. Every heart will melt, and every hand will go limp. Every spirit will faint, and every knee will turn to water.’ Yes, it is coming and it will surely happen, declares the Lord GOD.”
Context
5Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’ 6“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mí ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn. 7Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mí ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni Olúwa Olódùmarè wí.” 8Ọ̀rọ̀ Olúwa si tún tọ̀ mí wá pé: 9“Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ wí pé, èyí yìí ní Olúwa wí pé,
“ ‘Idà kan, idà kan,
tí a pọ́n, tí a sì dán pẹ̀lú,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.