Native Bible

Ecclesiastes 12:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí. “Gbogbo rẹ̀ asán ni!”

Ecclesiastes 12:8 in English

Ecclesiastes 12:8 · Berean Standard Bible

“Futility of futilities,” says the Teacher. “Everything is futile!”

Context

6Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já, tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́; kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun, tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga. 7Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà, tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni. 8“Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí. “Gbogbo rẹ̀ asán ni!” 9Kì í ṣe wí pé Oniwaasu jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. 10Oniwaasu wádìí láti rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó tọ̀nà, ohun tí ó kọ sì dúró ṣinṣin ó sì jẹ́ òtítọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.