Oniwaasu 12:7
Ecclesiastes 12:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà, tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni.
Ecclesiastes 12:7 in English
Ecclesiastes 12:7 · Berean Standard Bible
before the dust returns to the ground from which it came and the spirit returns to God who gave it.
Context
5Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga
àti ti ìfarapa ní ìgboro;
nígbà tí igi almondi yóò tanná
àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ
tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́
nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé
tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro. 6Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já,
tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́;
kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun,
tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga. 7Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà,
tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni. 8“Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí.
“Gbogbo rẹ̀ asán ni!” 9Kì í ṣe wí pé Oniwaasu jẹ́ ọlọ́gbọ́n nìkan, ṣùgbọ́n ó tún kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀. Ó rò ó dáradára ó sì ṣe àwárí, ó sì gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.