Native Bible

Ecclesiastes 12:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já, tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́; kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun, tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga.

Ecclesiastes 12:6 in English

Ecclesiastes 12:6 · Berean Standard Bible

Remember Him before the silver cord is snapped and the golden bowl is crushed, before the pitcher is shattered at the spring and the wheel is broken at the well,

Context

4nígbà tí ìlẹ̀kùn sí ìgboro yóò tì tí ariwo ọlọ yóò dákẹ́; nígbà tí àwọn ènìyàn yóò dìde sí ariwo àwọn ẹyẹ ṣùgbọ́n gbogbo orin wọn yóò máa lọ ilẹ̀. 5Nígbà tí ènìyàn yóò bẹ̀rù ibi gíga àti ti ìfarapa ní ìgboro; nígbà tí igi almondi yóò tanná àti tí ẹlẹ́ǹgà yóò wọ́ ara rẹ̀ lọ tí ìfẹ́ kò sì ní ru sókè mọ́ nígbà náà ni ènìyàn yóò lọ ilé rẹ́ ayérayé tí àwọn aṣọ̀fọ̀ yóò máa rìn kiri ìgboro. 6Rántí rẹ̀ kí okùn fàdákà tó já, tàbí kí ọpọ́n wúrà tó fọ́; kí iṣà tó fọ́ níbi ìsun, tàbí kí àyíká kẹ̀kẹ́ kí ó tó kán níbi kànga. 7Tí erùpẹ̀ yóò sì padà sí ilẹ̀ ibi tí ó ti wà, tí ẹ̀mí yóò sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tí ó fi í fún ni. 8“Asán! Asán!” ni Oniwaasu wí. “Gbogbo rẹ̀ asán ni!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.