Deuteronomi 33:28
Deuteronomy 33:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà, orísun Jakọbu nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.
Deuteronomy 33:28 in English
Deuteronomy 33:28 · Berean Standard Bible
So Israel dwells securely; the fountain of Jacob lives untroubled in a land of grain and new wine, where even the heavens drip with dew.
Context
26“Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,
ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ
àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀. 27Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,
àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.
Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,
ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’ 28Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,
orísun Jakọbu nìkan
ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,
níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀. 29Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,
ta ni ó dàbí rẹ,
ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa?
Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀
àti idà ọláńlá rẹ̀.
Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,
ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.