Native Bible

Deuteronomy 33:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’

Deuteronomy 33:27 in English

Deuteronomy 33:27 · Berean Standard Bible

The eternal God is your dwelling place, and underneath are the everlasting arms. He drives out the enemy before you, giving the command, ‘Destroy him!’

Context

25Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ, agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀. 26“Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀. 27Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’ 28Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà, orísun Jakọbu nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀. 29Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli, ta ni ó dàbí rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọláńlá rẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.