Native Bible

Deuteronomy 33:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli, ta ni ó dàbí rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọláńlá rẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”

Deuteronomy 33:29 in English

Deuteronomy 33:29 · Berean Standard Bible

Blessed are you, O Israel! Who is like you, a people saved by the LORD? He is the shield that protects you, the sword in which you boast. Your enemies will cower before you, and you shall trample their high places.”

Context

27Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’ 28Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà, orísun Jakọbu nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀. 29Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli, ta ni ó dàbí rẹ, ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀ àti idà ọláńlá rẹ̀. Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ, ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.