Native Bible

Deuteronomy 33:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀.

Deuteronomy 33:26 in English

Deuteronomy 33:26 · Berean Standard Bible

“There is none like the God of Jeshurun, who rides the heavens to your aid, and the clouds in His majesty.

Context

24Ní ti Aṣeri ó wí pé, “Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri; jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró. 25Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ, agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀. 26“Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹ àti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀. 27Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ, àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà. Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ, ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’ 28Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà, orísun Jakọbu nìkan ní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì, níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.