Deuteronomi 32:9
Deuteronomy 32:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀, Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.
Deuteronomy 32:9 in English
Deuteronomy 32:9 · Berean Standard Bible
But the LORD’s portion is His people, Jacob His allotted inheritance.
Context
7Rántí ìgbà láéláé;
wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.
Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,
àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ. 8Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,
nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,
ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn
gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli. 9Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,
Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀. 10Ní aginjù ni ó ti rí i,
ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí.
Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀,
ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀. 11Bí idì ti í ru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ń
rábàbà sórí ọmọ rẹ̀,
tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sì
gbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.