Deuteronomi 32:7
Deuteronomy 32:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Rántí ìgbà láéláé; wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá. Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ, àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.
Deuteronomy 32:7 in English
Deuteronomy 32:7 · Berean Standard Bible
Remember the days of old; consider the years long past. Ask your father, and he will tell you, your elders, and they will inform you.
Context
5Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;
fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò. 6Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,
ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?
Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,
tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín? 7Rántí ìgbà láéláé;
wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.
Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,
àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ. 8Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn,
nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,
ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn
gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli. 9Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,
Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.