Native Bible

Deuteronomy 32:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn, ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.

Deuteronomy 32:8 in English

Deuteronomy 32:8 · Berean Standard Bible

When the Most High gave the nations their inheritance, when He divided the sons of man, He set the boundaries of the peoples according to the number of the sons of God.*

Context

6Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn? Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín? 7Rántí ìgbà láéláé; wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá. Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ, àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ. 8Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn, ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli. 9Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀, Jakọbu ni ìpín ìní i rẹ̀. 10Ní aginjù ni ó ti rí i, ní aginjù níbi tí ẹranko kò sí. Ó yíká, ó sì tọ́jú rẹ̀, ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.