Native Bible

Deuteronomy 32:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn? Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?

Deuteronomy 32:6 in English

Deuteronomy 32:6 · Berean Standard Bible

Is this how you repay the LORD, O foolish and senseless people? Is He not your Father and Creator? Has He not made you and established you?

Context

4Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun. 5Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀; fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò. 6Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn? Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín? 7Rántí ìgbà láéláé; wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá. Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ, àwọn àgbàgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ. 8Nígbà tí Ọ̀gá-ògo fi ogún àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn, ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.