Native Bible

Deuteronomy 32:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.

Deuteronomy 32:4 in English

Deuteronomy 32:4 · Berean Standard Bible

He is the Rock, His work is perfect; all His ways are just. A God of faithfulness without injustice, righteous and upright is He.

Context

2Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò, kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì, bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun, bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn. 3Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa. Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa! 4Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé, gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo. Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan, Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun. 5Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀; fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò. 6Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn? Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín, tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.