Deuteronomi 32:3
Deuteronomy 32:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa. Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa!
Deuteronomy 32:3 in English
Deuteronomy 32:3 · Berean Standard Bible
For I will proclaim the name of the LORD. Ascribe greatness to our God!
Context
1Fetísílẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, èmi yóò sọ̀rọ̀;
ẹ gbọ́, ìwọ ayé, ọ̀rọ̀ ẹnu mi. 2Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ ọ̀ mi máa rọ̀ bí òjò,
kí àwọn ọ̀rọ̀ mi máa sọ̀kalẹ̀ bí ìrì,
bí òjò wíníwíní sára ewéko tuntun,
bí ọ̀wààrà òjò sára ohun ọ̀gbìn. 3Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa.
Ẹyin títóbi Ọlọ́run wa! 4Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,
gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.
Ọlọ́run olóòtítọ́ tí kò ṣe àṣìṣe kan,
Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun. 5Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;
fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,
ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apá kan tí ó sì dorí kodò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.