Amosi 9:10
Amos 9:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé, ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’
Amos 9:10 in English
Amos 9:10 · Berean Standard Bible
All the sinners among My people will die by the sword— all those who say, ‘Disaster will never draw near or confront us.’”
Context
8“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè
ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.
Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀.
Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,”
ni Olúwa wí. 9“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ,
Èmi yóò sì mi ilé Israẹli
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè
bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀
tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀. 10Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi
ni yóò ti ipa idà kú
gbogbo àwọn ti ń wí pé,
‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’ 11“Ní ọjọ́ náà ní
Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró,
Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya,
Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè,
Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì, 12kí wọn le jogún ìyókù Edomu
àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,”
ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.