Native Bible

Amos 9:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

kí wọn le jogún ìyókù Edomu àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,” ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí.

Amos 9:12 in English

Amos 9:12 · Berean Standard Bible

that they may possess the remnant of Edom and all the nations that bear My name,”* declares the LORD, who will do this.

Context

10Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi ni yóò ti ipa idà kú gbogbo àwọn ti ń wí pé, ‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’ 11“Ní ọjọ́ náà ní Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró, Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya, Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè, Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì, 12kí wọn le jogún ìyókù Edomu àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,” ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí. 13“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí, “tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá. Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá. Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀, tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké. 14Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀. “Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn. Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn wọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.