Amosi 9:13
Amos 9:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí, “tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá. Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá. Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀, tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké.
Amos 9:13 in English
Amos 9:13 · Berean Standard Bible
“Behold, the days are coming,” declares the LORD, “when the plowman will overtake the reaper and the treader of grapes, the sower of seed. The mountains will drip with sweet wine, with which all the hills will flow.
Context
11“Ní ọjọ́ náà ní
Èmi yóò gbé àgọ́ Dafidi tí ó wó ró,
Èmi yóò dí odi rẹ̀ tí ó ya,
Èmi yóò sì gbé ahoro rẹ̀ sókè,
Èmi yóò sì kọ bí ti ọjọ́ ìgbàanì, 12kí wọn le jogún ìyókù Edomu
àti gbogbo àwọn kèfèrí, ti a ń pè nípa orúkọ mi,”
ni Olúwa, ẹni tí yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí wí. 13“Ọjọ́ náà ń bọ,” ni Olúwa wí,
“tí ẹni tí ń tulẹ̀ yóò lé ẹni tí ń kórè bá.
Tí ẹni tí ń fún èso àjàrà yóò lé ẹni tí ń gbìn bá.
Àwọn òkè ńlá yóò sì kán ọtí wáìnì sílẹ̀,
tí yóò sì sàn láti ara àwọn òkè kéékèèké. 14Èmi yóò si tún mú ìgbèkùn Israẹli ènìyàn mi padà bọ̀.
“Wọn yóò sì kọ́ ahoro ìlú, wọn yóò sì máa gbé inú wọn.
Wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì mu ọtí wáìnì wọn
wọn yóò sì ṣe ọgbà pẹ̀lú, wọn yóò sì jẹ èso inú wọn. 15Èmi yóò gbin Israẹli sí orí ilẹ̀ rẹ̀.
A kì yóò sì fà wọn tu mọ́ láéláé
kúrò ni orí ilẹ̀ ti mo fi fún wọn,”
ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.