Amosi 9:8
Amos 9:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀. Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,” ni Olúwa wí.
Amos 9:8 in English
Amos 9:8 · Berean Standard Bible
Surely the eyes of the Lord GOD are on the sinful kingdom, and I will destroy it from the face of the earth. Yet I will not utterly destroy the house of Jacob,” declares the LORD.
Context
6Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run
ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé,
Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun
ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé
Olúwa ni orúkọ rẹ̀. 7“Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli
kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá
àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori
àti àwọn ará Aramu láti Kiri? 8“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè
ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀.
Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀.
Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,”
ni Olúwa wí. 9“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ,
Èmi yóò sì mi ilé Israẹli
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè
bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀
tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀. 10Gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn mi
ni yóò ti ipa idà kú
gbogbo àwọn ti ń wí pé,
‘Aburú kì yóò lé wa bá, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ká wa mọ́.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.