Native Bible

Amos 9:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?” ni Olúwa wí. “Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori àti àwọn ará Aramu láti Kiri?

Amos 9:7 in English

Amos 9:7 · Berean Standard Bible

“Are you not like the Cushites * to Me, O children of Israel?” declares the LORD. “Did I not bring Israel up from the land of Egypt, the Philistines from Caphtor,* and the Arameans from Kir?

Context

5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Naili tiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti. 6Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé, Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé Olúwa ni orúkọ rẹ̀. 7“Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?” ni Olúwa wí. “Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori àti àwọn ará Aramu láti Kiri? 8“Dájúdájú, ojú Olúwa Olódùmarè ń bẹ̀ lára ilẹ̀ ọba tó kún fún ẹ̀ṣẹ̀. Èmi yóò pa á run kúrò lórí ilẹ̀. Síbẹ̀, Èmi kò nípa ilé Jakọbu run pátápátá,” ni Olúwa wí. 9“Nítorí Èmi yóò pàṣẹ, Èmi yóò sì mi ilé Israẹli ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè bí a ti ń jọ nǹkan nínú ajọ̀ tí hóró kín ń kín kì yóò bọ́ sórí ilẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.