Amosi 9:5
Amos 9:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Naili tiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti.
Amos 9:5 in English
Amos 9:5 · Berean Standard Bible
The Lord GOD of Hosts, He who touches the earth and it melts, and all its dwellers mourn— all the land rises like the Nile, then sinks like the river of Egypt—
Context
3Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli,
èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀.
Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun,
láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán. 4Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọn
láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa.
“Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí,
kì í sì í ṣe fún rere.” 5Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Naili
tiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti. 6Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run
ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé,
Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun
ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé
Olúwa ni orúkọ rẹ̀. 7“Àbá ẹ̀yin ọmọ Israẹli
kò ha dàbí àwọn ọmọ Kuṣi sí mi?”
ni Olúwa wí.
“Èmi kò ha ti mú Israẹli gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá
àti àwọn Filistini láti ilẹ̀ Kafitori
àti àwọn ará Aramu láti Kiri?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.