Amosi 5:13
Amos 5:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí, nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.
Amos 5:13 in English
Amos 5:13 · Berean Standard Bible
Therefore, the prudent keep silent in such times, for the days are evil.
Context
11Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀
o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn.
Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé
ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn,
Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.
Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn. 12Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ
mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.
Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀
o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́. 13Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,
nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́. 14Wá rere, má ṣe wá búburú
kí ìwọ ba à le yè.
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.
Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí. 15Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere
dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́
bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára
yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.