Native Bible

Amos 5:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.

Amos 5:12 in English

Amos 5:12 · Berean Standard Bible

For I know that your transgressions are many and your sins are numerous. You oppress the righteous by taking bribes; you deprive the poor of justice in the gate.

Context

10Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́. 11Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn. Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn, Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn. 12Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó. Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́. 13Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí, nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́. 14Wá rere, má ṣe wá búburú kí ìwọ ba à le yè. Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ. Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.