Amosi 5:10
Amos 5:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.
Amos 5:10 in English
Amos 5:10 · Berean Standard Bible
There are those who hate the one who reproves in the gate and despise him who speaks with integrity.
Context
8Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni
ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀
tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀
ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀
tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀
Olúwa ni orúkọ rẹ̀, 9Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi
tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro. 10Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè
ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́. 11Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀
o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn.
Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé
ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn,
Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.
Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn. 12Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ
mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.
Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀
o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.