Native Bible

Amos 5:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.

Amos 5:9 in English

Amos 5:9 · Berean Standard Bible

He flashes destruction on the strong, so that fury comes upon the stronghold.

Context

7Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀. 8Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀ tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀ ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀ tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀ Olúwa ni orúkọ rẹ̀, 9Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro. 10Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́. 11Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀ o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn. Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn, Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà. Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.