Amosi 5:15
Amos 5:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.
Amos 5:15 in English
Amos 5:15 · Berean Standard Bible
Hate evil and love good; establish justice in the gate. Perhaps the LORD, the God of Hosts, will be gracious to the remnant of Joseph.”
Context
13Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,
nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́. 14Wá rere, má ṣe wá búburú
kí ìwọ ba à le yè.
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.
Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí. 15Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere
dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́
bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára
yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù. 16Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà
igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú.
A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún
àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún. 17Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà,
nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.