Native Bible

Amos 5:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà, nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,” ni Olúwa wí.

Amos 5:17 in English

Amos 5:17 · Berean Standard Bible

There will be wailing in all the vineyards, for I will pass through your midst,” says the LORD.

Context

15Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́ bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù. 16Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú. A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún. 17Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà, nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,” ni Olúwa wí. 18Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́ nítorí ọjọ́ Olúwa kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa? Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́. 19Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún, tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn. Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀ tí ejò sì bù ú ṣán.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.