2 Samuẹli 23:8
2 Samuel 23:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.
2 Samuel 23:8 in English
2 Samuel 23:8 · Berean Standard Bible
These are the names of David’s mighty men: Josheb-basshebeth the Tahchemonite * was chief of the Three.* He wielded his spear against * eight hundred men, whom he killed at one time.
Context
6Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì,
nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn. 7Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò
fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká;
wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.” 8Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní:
Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà. 9Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò. 10Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.