Native Bible

2 Samuel 23:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun.

2 Samuel 23:10 in English

2 Samuel 23:10 · Berean Standard Bible

but Eleazar stood his ground and struck the Philistines until his hand grew weary and stuck to his sword. The LORD brought about a great victory that day. Then the troops returned to him, but only to plunder the dead.

Context

8Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní: Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà. 9Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Eleasari ọmọ Dodo ará Ahohi, ọ̀kan nínú àwọn alágbára ọkùnrin mẹ́ta ti ó wà pẹ̀lú Dafidi, nígbà tí wọ́n pe àwọn Filistini ní ìjà, àwọn ọkùnrin Israẹli sì ti lọ kúrò. 10Òun sì dìde, ó sì kọlu àwọn Filistini títí ọwọ́ fi kún un, ọwọ́ rẹ̀ sì lẹ̀ mọ́ idà; Olúwa sì ṣiṣẹ́ ìgbàlà ńlá lọ́jọ́ náà, àwọn ènìyàn sì padà bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ láti kó ìkógun. 11Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni Ṣamma ọmọ Agee ará Harari, àwọn Filistini sì kó ara wọn jọ láti piyẹ́, oko kan sì wà níbẹ̀ tí ó kún fun lẹntili, àwọn ọmọ-ogun Israẹli sì sá kúrò níwájú àwọn Filistini. 12Ṣamma sì dúró láàrín méjì ilẹ̀ náà, ó sì gbà á sílẹ̀, ó sì pa àwọn Filistini Olúwa sì ṣe ìgbàlà ńlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.