2 Samuẹli 23:6
2 Samuel 23:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì, nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn.
2 Samuel 23:6 in English
2 Samuel 23:6 · Berean Standard Bible
But the worthless are all like thorns raked aside, for they can never be gathered by hand.
Context
4Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là,
òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu,
nígbà tí koríko tútù
bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’ 5“Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run,
ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,
tí a túnṣe nínú ohun gbogbo,
tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi,
ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà. 6Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì,
nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn. 7Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí yóò tọ́ wọn yóò
fi irin àti ọ̀pá ọ̀kọ̀ ṣagbára yí ara rẹ̀ ká;
wọ́n ó jóná lúúlúú níbìkan náà.” 8Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn akọni ọkùnrin tí Dafidi ní:
Joṣebu-Basṣebeti ará Takemoniti ni olórí àwọn balógun, òun sì ni akọni rẹ̀ tí ó pa ẹgbẹ̀rin (800) ènìyàn lẹ́ẹ̀kan náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.