2 Samuẹli 23:4
2 Samuel 23:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’
2 Samuel 23:4 in English
2 Samuel 23:4 · Berean Standard Bible
is like the light of the morning at sunrise of a cloudless dawn, the glistening after the rain on the sprouting grass of the earth.’
Context
2“Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi. 3Ọlọ́run Israẹli ni,
àpáta Israẹli sọ fún mi pé,
‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo,
tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 4Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là,
òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu,
nígbà tí koríko tútù
bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’ 5“Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run,
ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun,
tí a túnṣe nínú ohun gbogbo,
tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi,
ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà. 6Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ọmọ Beliali yóò dàbí ẹ̀gún ẹ̀wọ̀n tí a ṣá tì,
nítorí pé a kò lè fi ọwọ́ kó wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.