Native Bible

2 Samuel 23:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.

2 Samuel 23:3 in English

2 Samuel 23:3 · Berean Standard Bible

The God of Israel spoke; the Rock of Israel said to me, ‘He who rules the people with justice, who rules in the fear of God,

Context

1Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé, 2“Ẹ̀mí Olúwa sọ ọ̀rọ̀ nípa mi, ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ ní ahọ́n mi. 3Ọlọ́run Israẹli ni, àpáta Israẹli sọ fún mi pé, ‘Ẹnìkan ti ń ṣe alákòóso ènìyàn lódodo, tí ń ṣàkóso ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 4Yóò sì dàbí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nígbà tí oòrùn bá là, òwúrọ̀ tí kò ní ìkùùkuu, nígbà tí koríko tútù bá hù wá láti ilẹ̀ lẹ́yìn òjò.’ 5“Lóòtítọ́ ilé mi kò rí bẹ́ẹ̀ níwájú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó ti bá mi dá májẹ̀mú àìnípẹ̀kun, tí a túnṣe nínú ohun gbogbo, tí a sì pamọ́; nítorí pé gbogbo èyí ni ìgbàlà, àti gbogbo ìfẹ́ mi, ilé mi kò lè ṣe kí ó má dàgbà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.