Native Bible

1 Samuel 2:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Olúwa pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.

1 Samuel 2:6 in English

1 Samuel 2:6 · Berean Standard Bible

The LORD brings death and gives life; He brings down to Sheol and raises up.

Context

4“Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè. 5Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe, àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní. Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje. Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára. 6“Olúwa pa ó sì sọ di ààyè; ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde. 7Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀; ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. 8Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo, “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.