1 Samuẹli 2:4
1 Samuel 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́, àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè.
1 Samuel 2:4 in English
1 Samuel 2:4 · Berean Standard Bible
The bows of the mighty are broken, but the feeble are equipped with strength.
Context
2“Kò sí ẹni tí ó mọ́ bi Olúwa;
kò sí ẹlòmíràn bí kò ṣe ìwọ;
kò sì sí àpáta bi Ọlọ́run wa. 3“Má ṣe halẹ̀;
má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga ti ẹnu yín jáde
nítorí pé Ọlọ́run olùmọ̀ ni Olúwa,
láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá ni a ti ń wọn ìwà. 4“Ọ̀run àwọn alágbára ti ṣẹ́,
àwọn tí ó ṣe aláìlera ni a fi agbára dì ní àmùrè. 5Àwọn tí ó yọ̀ fún oúnjẹ ti fi ara wọn ṣe alágbàṣe,
àwọn tí ebi ń pa kò sì ṣe aláìní.
Tó bẹ́ẹ̀ tí àgàn fi bí méje.
Ẹni tí ó bímọ púpọ̀ sì di aláìlágbára. 6“Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;
ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.