1 Samuẹli 2:8
1 Samuel 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo, “Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn.
1 Samuel 2:8 in English
1 Samuel 2:8 · Berean Standard Bible
He raises the poor from the dust and lifts the needy from the ash heap. He seats them among princes and bestows on them a throne of honor. For the foundations of the earth are the LORD’s, and upon them He has set the world.
Context
6“Olúwa pa ó sì sọ di ààyè;
ó mú sọ̀kalẹ̀ lọ sí isà òkú, ó sì gbé dìde. 7Olúwa sọ di tálákà; ó sì sọ di ọlọ́rọ̀;
ó rẹ̀ sílẹ̀, ó sì gbé sókè. 8Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá,
ó gbé alágbe sókè láti orí òkìtì eérú wá,
láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé,
láti mu wọn jogún ìtẹ́ ògo,
“Nítorí pé ọ̀wọ́n ayé ti Olúwa ni,
ó sì ti gbé ayé ka orí wọn. 9Yóò pa ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́,
àwọn ènìyàn búburú ni yóò dákẹ́ ní òkùnkùn.
“Nípa agbára kò sí ọkùnrin tí yóò borí. 10A ó fọ́ àwọn ọ̀tá Olúwa túútúú;
láti ọ̀run wá ni yóò sán àrá sí wọn;
Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ òpin ayé.
“Yóò fi agbára fún ọba rẹ̀,
yóò si gbé ìwo ẹni àmì òróró rẹ̀ sókè.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.