Native Bible

Zephaniah 1:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé, àwọn tí ń sin ogun ọ̀run, àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra, tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.

Zephaniah 1:5 in English

Zephaniah 1:5 · Berean Standard Bible

those who bow on the rooftops to worship the host of heaven, those who bow down and swear by the LORD but also swear by Milcom,*

Context

3“Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò, àti ẹja inú Òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,” ni Olúwa wí. 4“Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, 5àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé, àwọn tí ń sin ogun ọ̀run, àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra, tí wọ́n sì ń fi Moleki búra. 6Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ Olúwa; àti àwọn tí kò tí wá Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.” 7Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa Olódùmarè, nítorí tí ọjọ́ Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀. Olúwa ti pèsè ẹbọ kan sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.