Sefaniah 1:3
Zephaniah 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò, àti ẹja inú Òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,” ni Olúwa wí.
Zephaniah 1:3 in English
Zephaniah 1:3 · Berean Standard Bible
“I will sweep away man and beast; I will sweep away the birds of the air, and the fish of the sea, and the idols with their wicked worshipers.* I will cut off mankind from the face of the earth,” declares the LORD.
Context
1Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Sefaniah ọmọ Kuṣi, ọmọ Gedaliah, ọmọ Amariah, ọmọ Hesekiah, ní ìgbà Josiah ọmọ Amoni ọba Juda. 2“Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò
lórí ilẹ̀ náà pátápátá,”
ni Olúwa wí. 3“Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò;
èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò, àti ẹja inú Òkun,
àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú;
èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,”
ni Olúwa wí. 4“Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Juda
àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu.
Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín yìí ìyókù àwọn Baali, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà
pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà, 5àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ lórí òrùlé,
àwọn tí ń sin ogun ọ̀run,
àwọn tó ń foríbalẹ̀, tí wọ́n sì ń fi Olúwa búra,
tí wọ́n sì ń fi Moleki búra.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.